Celine àti Afiba di àwátì lẹ́yìn àbẹ̀wò sílé ọ̀rẹ́kùnrin, mọ̀lẹ́bí bá figbe ta - BBC News Yorùbá (2024)

Celine àti Afiba di àwátì lẹ́yìn àbẹ̀wò sílé ọ̀rẹ́kùnrin, mọ̀lẹ́bí bá figbe ta - BBC News Yorùbá (1)

Oríṣun àwòrán, @CELINE NDUDIM/AFIBA TANDOR FAMILY

Ẹbẹ ni ẹbi awọn ọmọbinrin meji kan, Celine Ndubim ati Afiba Tandor ti oun jẹ ọmọ orilede Ghana n bẹ ọlọpaa Naijriria bayii, lẹyin ti wọn di awati nipinlẹ Abia ti wọn ti lọọ ki ọkunrin kan.

Andrew Amechi ni wọn pe orukọ ọkunrin naa.

Ilu Aba, ni ipinlẹ Abia ni Celine ati Afiba lọ gẹgẹ bi Tessy to jẹ ẹgbọn fun Celine ṣe ṣalaye fun BBC.

O ṣalaye siwaju si i pe lati ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu karun un ọdun 2024 ni wọn ti kede pe wọn n wa awọn mejeeji yii.

Laipẹ lẹyin eyi ni ileeṣẹ ọlọpaa kede pe awọn ti ri oku kan lagbegbe ibi ti Celine ati Afiba wa ọkunrin lọ ti wn si ni awọn woye pe oku arakunrin Andrew ti wọn wa lọ ni, amọṣa yoo di igba ti wọn ba ṣe ayẹwo tan ki wọn to le sọ boya oun ni lootọ.

Agbegbe ti wọn wa gbẹyin ko too di pe ẹnikẹni ko ri wọn pe lorii foonu mọ ni awọn ọlọpaa ti ri oku naa bi wọn ṣe sọ.

Ṣugbọn awọn ẹbi wọn ni awọn gbagbọ pe wọn ko ti i ku, wọn ni ki ijọba Naijiria gba awọn.

  • Njẹ́ o mọ̀ pé ewu wà fún àwọn tó máa n la ẹnu sílẹ̀ lójú oorun? Ìdí abájọ rèé

  • Ẹ wo àwọn ìlànà tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ tún fún ìjọba lórí ọ̀rọ̀ owó oṣù

Báwo ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣe ṣẹlẹ̀ gan-an?

Celine àti Afiba di àwátì lẹ́yìn àbẹ̀wò sílé ọ̀rẹ́kùnrin, mọ̀lẹ́bí bá figbe ta - BBC News Yorùbá (2)

Tessy Ndudim, ṣalaye pe lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹrin ọdun 2024 loun gba ipe kan lati ọdọ ọrẹ aburo oun kan, pe ọkunrin ti Celine ati Afiba lọọ ba ni Aba ti ji wọn gbe.

O ni ọrẹ wọn naa sọ pe oun ti lọ si Aba lati fọrọ naa to ọlọpaa leti.

O ni Celine ati Afiba fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si ọrẹ wọn pe Andrew Amechi, ọkunrin tawọn lọọ ki ti ji awọn gbe o.

Ninu atẹjiṣẹ naa ni wọn ti ni ki ọrẹ awọn lọọ fi ohun to ṣẹlẹ to ọlọpaa leti.

Ki wọn si ke gbajare ki gbogbo aye gbọ.

Tessy sọ pe oun pẹlu fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti ṣugbọn wọn ko ja a kunra.

" O yẹ kawọn ọlọpaa le gba aburo mi ati ọrẹ ẹ silẹ lọsẹ ti mo sọ ohun to ṣẹlẹ fun wọn, ṣugbọn wọn ko ja a kunra.

‘’Wọn sọ fun mi pe eto ni gbogbo ẹ, pe ọrọ yẹn ko ṣee kanju ṣe.

‘’Wọn sọ fun mi pe ijamba kankan ko ni i ṣe wọn nibikibi ti wọn ba wa.

"Ṣugbọn mo taku, wọn si pada lọọ wa wọn lagbegbe ti wọn ni awọn wa gbẹyin.

‘’Wọn wo awọn ile to wa nibẹ, mo ni ki wọn wo ile kan ta a ri fidio ẹ, nitori mo ri mọto kan to jọ eyi ti wọn fi gbe wọn lọ si otẹẹli Aba yẹn.

Awọn ọlọpaa lọọ wo o, wọn lawọn o ri nnkan kan"

  • 'Ọmọ mi kú láàárín wákàtí mẹ́fà tí wọ́n dúnkokò láti fi fọ́tò ìhòhò rẹ̀ s'órí ayélujára'

  • Opay, Kuda, gbe ìlànà tuntun kalẹ̀ fún àwọn oníbàárà lẹ́yìn tí CBN gbẹ́sẹ̀ lórí òfin tó fi dè wọ́n

’Ìyá wa ò gbádùn mọ́ látìgbà tí ọ̀rọ̀ yìí ti ṣẹlẹ̀’

Tessy ṣalaye pe latigba ti aburo oun ti di awati ni iya awọn ko ti ni alaafia mọ.

O ni gbogbo ẹbi awọn ni idaamu ti ba.

O waa rawọ ẹbẹ si awọn ọlọpaa Umuahia, lati yanju ọrọ yii kia, ki awọn ọmọ meji naa le pada wale pẹlu alaafia.

Bakan naa lo ni kijọba ipinlẹ Abia ma dakẹ, ki wọn wa Andrew Amechi to gbe awọn aburo oun pamọ pẹlu.

‘Mi ò gbàgbọ́ pé ìyàwó mi ti kú’ -Ọkọ Afiba

Celine àti Afiba di àwátì lẹ́yìn àbẹ̀wò sílé ọ̀rẹ́kùnrin, mọ̀lẹ́bí bá figbe ta - BBC News Yorùbá (3)

Ọmọ Ghana ni Afiba Tandor ni tiẹ, oun ati Celine Ndudim toun jẹ ọmọ Naijiria ni wọn jọ kuro ni Ghana wa si Naijiria.

Celine lo ni kawọn jọ lọọ ki Andrew Amechi ti wọn lo ji wọn gbe yii.

Ṣugbọn ko pẹ ti wọn de ọdọ ọkunrin naa ti wọn fi fi atẹjiṣẹ inira ranṣẹ pe awọn ti há.

Afiba lọkọ ni Ghana to ti wa.

Ọkọ rẹ to ni ka ma darukọ oun, sọ fun BBC pe inu oun o dun si bawọn ọlọpaa Naijiria ṣe n fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ yii.

O ni oun ko gbagbọ pe iyawo oun ti ku, bo tilẹ jẹ pe oṣu kan ti kọja tawọn ọlọpaa ti wa lẹnu ẹ.

Ọkọ Afiba sọ pe oun ṣi n ba iyawo oun sọrọ nigba to wa ni Naijiria, ki wọn too lọọ ki Amechi.

‘’Lati Accra ni wọn ti lọ si Eko, lẹyin naa ni wọn tirafu lọ si Owerri, ki wọn too lọ si Port Harcourt ati Aba lati ri ọrẹ Celine, to wa di pe mi o ri wọn ba sọrọ mọ.

‘’Emi o gba pe iyawo mi ti ku o. Bi wọn ko ba le fi ẹri DNA to ni iyawo mi lo ku han, mi o gbagbọ pe o ti ku rara’’

Bẹẹ ni ọkọ Afiba wi.

O loun ti fi iṣẹlẹ naa to awọn alaṣẹ leti ni Ghana, ati ẹka to n ri si irianjo ni Naijiria, ki wọn ṣaanu oun lori ọrọ Afiba to sọnu si Naijiria.

  • Báwo ni àwọn oníbàárà Heritage Bank ṣe lè rí owó wọn gbà padà?

  • Olóòtú ìjọba India, Narendra Modi jáwé olúborí nínú ìdìbò fún sáà kéta

Ṣé lóòótọ́ ni pé Andrew Amechi ti kú?

Lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu karun-un ọdun 2024, iroyin jade pe Andrew Amechi jade laye lasiko tawọn ọlọpaa n gbe e lati Aba lọ si Abuja.

Wọn ni awọn fijilante kan ni wọn da ibọn bolẹ ti Amechi fi ku.

Iroyin si tun ro o pe awọn to pa Amechi ti wa lahaamọ ọlọpaa.

Ṣugbọn ọkọ Afiba loun ko gba pe Amechi ku, afi bawọn ọlọpaa ba le fi oku rẹ han oun.

O ni awọn ijọba Gẹẹsi gan-an n wa Andrew Amechi tori iṣẹ ọwọ rẹ.

O sọ pe ọlọpaa Naijiria ko gbọdọ fọwọ yẹpẹrẹ mu iru eeyan bẹẹ ti yoo fi waa ku.

Lori oku tawọn ọlọpaa ni awọn ri, awọn ẹbi Afiba ati ti Celine sọ pe awọn ko gba pe ti ọmọ awọn ni.

Wọn ni oku ti wọn ti ge ori rẹ lọ pẹlu awọn ẹya ara mi-in, to ti jẹra kọja idanimọ lawọn ọlọpaa n ṣafihan.

Ohun to foju han ni pe iṣẹlẹ yii kẹnu pupọ, bẹẹ ni igbinyanju wa lati ba Alukoro ọlọpaa Naijiria sọrọ ko ti i so eso rere.

A o maa mu itẹsiwaju iroyin naa wa bi ọlọpaa ba fi ohunkohun lede nipa rẹ ati bo ba ṣe n lọ.

Celine àti Afiba di àwátì lẹ́yìn àbẹ̀wò sílé ọ̀rẹ́kùnrin, mọ̀lẹ́bí bá figbe ta - BBC News Yorùbá (2024)

References

Top Articles
Latest Posts
Article information

Author: Neely Ledner

Last Updated:

Views: 5916

Rating: 4.1 / 5 (42 voted)

Reviews: 81% of readers found this page helpful

Author information

Name: Neely Ledner

Birthday: 1998-06-09

Address: 443 Barrows Terrace, New Jodyberg, CO 57462-5329

Phone: +2433516856029

Job: Central Legal Facilitator

Hobby: Backpacking, Jogging, Magic, Driving, Macrame, Embroidery, Foraging

Introduction: My name is Neely Ledner, I am a bright, determined, beautiful, adventurous, adventurous, spotless, calm person who loves writing and wants to share my knowledge and understanding with you.